Rhapsody Global Club ( Mandate 1B ROR Influences )
Rhapsody Global Club ( Mandate 1B ROR Influences )
March 1, 2025 at 05:02 PM
Rhapsody Yoruba Sun Mar 02 2025 NI MÍMỌ̀ DÍẸ̀ SII NÍPA KRISTÌ NÍNÚ RẸ Ọ̀rọ̀ náà sì di ara, òun sì ń bá wa gbé. Àwa sì ti rí ògo rẹ̀ , àní ògo ọmọ rẹ kan ṣoṣo, tí ó ti ọ̀ dọ̀ Baba wá, ó kún fún oore-ọ̀ fẹ́ àti òtítọ́ " (Johannu 1:14). Nigbàtí a ba sọ pé Kristiẹni jẹ́ ọ̀ kan nínú ẹnití Kristi ńgbe inú re ̣ ̀ , ìṣòro ibe ̣ ̀ náà ni pé ọ̀ pọ̀ lọpọ̀ paapaa kò mọ ohun tí Kristi túmọ sí tàbi ẹ̀ niti Kristi jẹ́ . Kíni ìtumọ̀ gbolóhùn ọ̀ rọ̀ yí Kristi? Kristi jẹ́ gbolóhùn ọ̀ rọ̀ Hébérù fún Mèsáýà, Mèsáyà ̀ sì túmọ̀ sí Ẹni Àmì Òróró. Nínú Májẹ̀ mú Láéláé, wọ́ n ń pè é ní Mèsáyà, àti nínú Májẹ̀ mú Titun, wọ́ n ń pè é ní Kristi, ṣùgbọ́ n àwọn méjèèjì ń tọ́ ka sí ẹni kan náà. Ẹni tí àwọn Júù gbọ́ pé ó jẹ́ Mèsáyà ni ohun tí Wòlíì Dáníẹ́ lì pè ní "Ọmọ Ènìyàn." Nígbà tí Jésù tọ́ ka sí Ara Rẹ̀ gẹ́ gẹ́ bí "Ọmọ Ènìyàn" tí a óò "gbé sókè," tí ó túmọ̀ sí àgbélébùú, àwọn Júù bi Í léèrè, wọ́ n béèrè pé, "Ta ni Ọmọ Ènìyàn yìí?" Wọ́ n rò pé Kristi yóò wà láàyè títí láé. Bíbélì sọ nínú Johannù 12:23, 32-34 pé: "... Jesu dá wọn lóhùn, ó ní, Wákàtí náà dé, tí a o se Ọmọ ènìyàn logo….. Àti èmi, bí a bá gbé mi sókè kúrò ní ayé, èmi ó fa gbogbo ènìyàn sọ́ dọ̀ ara mi!” Ṣùgbọ́ n ó wí èyí, ó ń ṣe àpẹẹrẹ irú ikú tí òun yóò kú.Nítorí náà àwọn ìjọ ènìyàn dá a lóhùn pé, “Àwa gbọ́ nínú òfin pé, Kristi wà títí láéláé: ìwọ ha ṣe wí pé, ‘A ó gbé ọmọ ènìyàn sókè? Ta ni ó ń jẹ́ ọmọ ènìyàn yìí’?Jésù tọ́ ka sí àwọn àsọtẹ́ lẹ̀ Dáníẹ́ lì èyí sì jẹ́ rìí fún wọn. Gbólóhùn Ọ̀rọ̀ Ọmọ Ènìyàn jẹ́ àpèjúwe Ọmọ Ọlọ́ run. Ṣùgbọ́ n Ọmọ Ọlọ́ run kò túmọ̀ sí "ẹni tí Ọlọ́ run bí"; Kàkà bẹ́ ẹ̀ , ó túmọ̀ sí Ọlọ́ run nínú ẹran ara ènìyàn. Ìdí nìyí tí Jésù fi sọ pé Òun ni Ọmọ Ọlọ́ run, àwọn olórí Júù fi ẹ̀ sùn ọ̀ rọ̀ òdì kàn án. Wọ́ n sọ pé, "... Àwa kò sọ ọ́ lókùúta nítorí iṣẹ́ rere, ṣùgbọ́ n nítorí ọ̀ rọ̀ - òdì: àti nítorí ìwọ tí í ṣe ènìyàn ń fi ara rẹ pe Ọlọ́ run " (Jòhánnù 10:33). Wọ́ n mọ̀ pé Mèsáyà, ni Ọlọ́ run farahàn nínú ẹran ara, ẹni tí Jésù kéde ara rẹ̀ gẹ́ gẹ́ bí pe Òun ni. Nígbà tí o bá sọ pé Jésù ni Kristi, o túmọ̀ sí pé Jésù ni Ọlọ́ run tí ó farahàn nínú ẹran ara. Ohun tí wọ́ n kàn án mọ́ àgbélébùú fún nìyí. Má gbàgbé rẹ̀ láéláé. Nínú àpẹẹrẹ mìíràn, gẹ́ gẹ́ bí Maakù 14:61-64 ṣe sọ fún wa, nígbà tí àlùfáà àgbà bi í ní tààrà pé, "Ṣé ìwọ ni Kristi?" Jésù sì dáhùn ní ìdánilójú, àlùfáà àgbà sì fa aṣọ rẹ̀ ya, ó pè é ni ọ̀ rọ̀ òdì. Ìkéde náà yọrí sí ìdájọ́ ikú fún Jésù. Ṣùgbọ́ n Jésù sọ òótọ́ . Òun ni Kristi lóòótọ́ . Mesáyà tàbí Kristi ni Ọlọ́ run nínú ara. Nígbà tí o sì gba Kristi, ìgbé ayé Ọlọ́ run rẹ̀ rọ́ pò ẹ̀ mí ènìyàn rẹ, ó sì farahàn nínú rẹ. O di Kristi-nínú-rẹ. Kólóse 1:27 sọ pé, "... Kristi nínú rẹ, ìrètí ògo. "Èyí ni ògo àti ìse pàtàkì ẹ̀ sìn Krístẹ́ nì - Kristi nínú rẹ! Mọ̀ o ̣ ́ kí o sì mọ òtítọ́ yìí lónìí, ju ti tẹ́ lẹ̀ lọ. Prayer / Confession Baba mi olùfẹ́ , o ṣeun fún ìfihàn ti ẹniti Kristi jẹ́ - Ọlọ́ run farahàn ninú ara. Mo kéde pé Kristi ń gbé inú mi, àti ìye re ̣̀ mímo ̣ ́ ni a ṣe àfihàn ni gbogbo ara ti isẹ̀ dá mi. Mò rìn nínú ìmọ̀òtítọ́ yìí, mímú ète rẹ sẹ àti fífi ògo rẹ hàn sí ayé ní Orúkọ Jésù. Àmín. Further study Kolose 1:26-27; Johannu 1:14 NIV; 1 Timoteu 3:16 1-year bible reading plan Marku 9:33-50 & Numeri 9-10 2-year bible reading plan Matteu 19:13-22 & Eksodu 11 WhatsApp Chanel for rhapsody Translation : https://whatsapp.com/channel/0029Va9SJ9OHFxP0Xh4KCN3F

Comments