Rhapsody Global Club ( Mandate 1B ROR Influences )
Rhapsody Global Club ( Mandate 1B ROR Influences )
June 13, 2025 at 06:54 PM
Rhapsody Yoruba Sat Jun 14 2025 AGBÁRA TI ÌRAN ÀTI FÍFOJÚ INÚ WÒ ̀ Jákọ́ bù sì mú ọpá igi-poplarì tútù, ati igi haselì ati igi kesnuti; ó sì bò wọn ni abófin, o sì mú kí funfun tí ó wà lára àwọn ọpá nà hàn (Jẹ́ nẹ́ sìsi 30:37). Ì tàn Jákọbù nínú Jẹ́ nẹ́ sìsi 30 àti 31 jẹ́ìfihàn tí ó fani mọ́ ra nípa agbára ìran àti fífojú inú wò ̀. Nígbà tí Jakọbu gbà láti ṣiṣẹ́ fún Labani, wọ́ n ṣèlérí àwọn màlúù rẹ̀ gẹ́ gẹ́ bí owó oṣù. Síbẹ̀ síbẹ̀ , Labani yí àwọn òfin náà padà léraléra ó sì tàn Jako ̣ ́ bù jẹ. Ṣùgbọ́ n Jakọbù, nípasẹ̀ ọgbọ́ n Ọlọ́ run àti ọgbọ́ n àtinúdá, yí ipò náà padà. Jako ̣ ́ bù mú ọ̀ pá láti inúigi- poplari aláwọ̀ ewé, ati igi haselì ati igi kesnuti; ó sì bò wọn ni abófin, o sì mú kí funfun tí ó wà lára àwọn ọpá nà hàn. Ó gbé àwọn ọ̀ pá wọ̀ nyí sínú àwọn àgbàrá omi níbi tí àwọn agbo ẹran ti wá mu. Bí àwọn ẹranko náà ṣe ń bá ara wọn lòpọ̀ níwájú àwọn ọ̀ pá, wọ́ n bí ọmọ tí Jakọbu fẹ́ gan-an. Nígbà tó yá, Jakọbu kò nílò àwọn ọ̀ pá náà mọ́ . Ó ya àwọn ọ̀ dọ́ - agùtàn náà sọ́ tọ̀ ,oní-tototo, àti àwọn ẹranko alámì ó sì gbé wọn síwájú màlúù tó lágbára. Nípa ṣíṣe èyí, ó dá ìran fún àwọn agbo ẹran, wọ́ n sì ṣe àgbéjáde re ̣ ̀ gẹ́ gẹ́ bí ohun tí wọ́ n rí. Ọ̀nà Jakọbù jẹ́ ìfihàn agbára àtinúdá ìran. Ó lo agbára ìfojunúwo rẹ̀ láti ní ipa lórí èsì náà. Nígbà tí àwọn màlúù tí ó lágbára bá lóyún, Jakọbu gbé ọ̀ pá náà síwájú wọn, ó ń rí i dájú pé wọ́ n bí àwọn ọmọ tí ó lágbára, tí ó wuyì jáde. Nígbà tí àwọn màlúù náà bá se aláìlera, kò kin ńlo ọ̀ pá náà, nítorí náà àwọn aláìlera jẹ́ ti Labani. Lẹ́ yìn ìgbà díẹ̀ , àwọn agbo ẹran Jakọbu túbọ̀ lágbára sí i, wọ́ n sì pọ̀ sí i, nígbà tí Labani ṣì wà ní aláìlera. Àṣeyọrí Jakọbu jẹ́ nípa ìfihàn Ọlọ́ run. Nínú àlá kan, ó rí àwọn àgbò tí wọ́ n gun sórí àwọn màlúù gẹ́ gẹ́ bí tototo, abilà, àti alámì. Angẹli kan fìdí ìran yìí múlẹ̀ , ó ní, "Gbé ojú rẹ sókè báyìí kí o sì wò ó, gbogbo àwọn àgbò tí wọ́ n gun agbo ẹran ni wọ́ n ńgun, tí o ní tototo, tí wọ́ n sì rí bi àwọ̀ eérú..." (Jẹnẹsisi 31:12c NKJV). Báwo ni èyí ṣe ṣe pàtàkì tó! O ní agbára láti ṣẹ̀ dá ọjọ́ iwájú tí o fẹ́ nípa ṣíṣe àfojúsùn lórí ohun tí o fẹ́ rí. Ṣẹ̀ dá ìran tí o fẹ́ pẹ̀ lú ọkàn rẹ. Nipasẹ̀ Ọ̀rọ̀ àti agbára ti Ẹ̀mi Mímọ́ tí ńsiṣẹ ninú rẹ, o le ṣẹ̀ dá tàbí ṣe àpẹẹrẹ òtítọ́ ti ara rẹ. Hallelujah! Prayer / Confession Baba mi olùfẹ, o ṣeun tó fún mi ni agbára láti rii àti ṣẹ̀ dá ọjọ́ iwájú ti mo fẹ́ nipasẹ agbára ìran ati nipasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ. Bí mo ṣe ń lo agbára ìfòjúnúwò mi, tí ó ní ìmísí láti ọwọ́ Ẹ̀mí rẹ, mo kọ́ ayé mi ní ìbámu pẹ̀ lú ète Ọlọ́ run, pẹ̀ lú ìṣẹ́ gun àti ìgbésókè ní gbogbo agbègbè. Mo ni agbára láti ni ipa lórí ayé mi àti mú ìpinnu mi ṣẹ, ni Orúkọ Jésù. Àmín. Further study Genesisi 13:14-17; Habakkuku 2:2; Efesu 3:20 1-year bible reading plan IŒe awön Aposteli 4:32-5:1-11 & 2 Kronika 20-22 2-year bible reading plan Luku 1:39-56 & Deuteronomi 12 WhatsApp Chanel for rhapsody Translation : https://whatsapp.com/channel/0029Va9SJ9OHFxP0Xh4KCN3F

Comments